Onídájọ́ 4:16-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Bárákì àti àwọn ogun rẹ̀ sì lé àwọn ọ̀tá náà, àwọn ọmọ ogun orílẹ̀ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn títí dé Háróṣétì ti àwọn orílẹ̀ èdè, títí ó fi pa gbogbo àwọn ọmọ ogun Ṣísérà kò sí ọ̀kan tí ó lè sálà tàbí tí ó wà láàyè.

17. Ṣùgbọ́n Ṣísérà ti fi ẹṣẹ̀ sá lọ sí àgọ́ Jáélìa aya Hébérì ẹ̀yà Kénì: nítorí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àlàáfíà wà láàárin Jábínì ọba Háṣórì àti ìdílé Hébérì ti ẹ̀yà Kénì.

18. Jáélì sì jáde síta láti pàdé Sísérà, ó sì wí fún-un pé, “Wọlé sínú àgọ́ mi, Olúwa mi, wọlé wá má ṣe bẹ̀rù nítorí pé ààbò ń bẹ fún ọ.” Ó sì yà sínú àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ bò ó.

19. Sísérà wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ́ mí, jọ̀wọ́ fún mi ní omi mu.” Ó sì sí awọ wàrà kan, ó sì fún-un mu ó sì tún daṣọ bò ó padà.

20. Sísérà sọ fún Jáélì pé, “Kí ó dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́, àti pé bí ẹnikẹ́ni bá béèrè bóyá òun wà níbẹ̀ kí ó sọ pé, ‘Kò sí ẹnìkankan ní ibẹ̀.’ ”

21. Ṣùgbọ́n Jáélì ìyàwó Hébérì mú ìṣó àgọ́ tí ó mú àti òlù ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì yọ́ wọ inú ibi tí ó ṣùn, nígbà tí ó ti sùn fọnfọn, nígbà náà ni ó kan ìṣó náà mọ́ òkè ìpéǹpéjú rẹ̀, ó sì wọlé ṣinṣin ó sì kú.

22. Nígbà tí Bárákì dé bí ó ti ń lépa Sísérà, Jáélì láti pàdé rẹ̀, wá, èmi yóò fi ẹni tí ìwọ ń wá hàn ọ́, báyìí ni ó tẹ̀lé e wọ inú àgọ́ lọ, kíyèsí Ṣísérà dùbúlẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú ìṣó àgọ́ ní agbárí rẹ̀ tí a ti kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin tí ó sì ti kú.

23. Ní ọjọ́ náà ni Ọlọ́run ṣẹ́gun Jábínì ọba àwọn ará Kénánì ní iwájú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

24. Ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì le, ó sì ń lágbára síwájú àti síwájú sí i lára Jábínì ọba Kénánì, títí wọ́n fi run òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.

Onídájọ́ 4