1. Lẹ́yìn ikú Éhúdù, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì sì tún ṣẹ̀, wọ́n ṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa.
2. Nítorí náà Olúwa jẹ́kí Jábínì, ọba àwọn Kénánì, ẹni tí ó jọba ní Haṣórì, ṣẹ́gun wọn. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Ṣísérà ẹni tí ń gbé Hároṣeti-Hágóyímù.
3. Nítorí tí ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) kẹ̀kẹ́ ogun irin, ó sì ń pọ́n Ísírẹ́lì lójú gidigidi fún ogún ọdún. Ísírẹ́lì ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́.