Onídájọ́ 21:23-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Èyí sì ni ohun tí àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣe. Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin náà ń jó lọ́wọ́, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan mú ọmọbìnrin kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì gbé e lọ láti di aya rẹ̀. Wọ́n sì padà sí ilẹ̀ ìní wọn, wọ́n sì tún àwọn ìlú náà kọ́, wọ́n sì tẹ̀dó sínú wọn.

24. Ní àkókò náa, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ibẹ̀, wọ́n lọ sí ilé àti ẹ̀yà rẹ̀ olúkúlùkù sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.

25. Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, kò sí ọba ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì; olúkúlùkù sì ń ṣe bí ó ti tọ́ ní ojú ara rẹ̀.

Onídájọ́ 21