Onídájọ́ 21:11-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Wọ́n ní, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe, ẹ pa gbogbo ọkùnrin àti gbogbo obìnrin tí kì í ṣe wúndíá.”

12. Wọ́n rí àwọn irinwó (400) ọ̀dọ́bìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí nínú àwọn olùgbé Jabesi-Gílíádì, wọ́n sì mú wọn lọ sí ibùdó ní Ṣílò àwọn ará Kénánì.

13. Gbogbo ìjọ àwọn ènìyàn sì ránṣẹ́ àlàáfíà sí àwọn Bẹ́ńjámínì ní ihò àpáta Rímónì.

14. Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì náà sì padà ní àkókò náà, wọ́n sì fún wọn ní àwọn obìnrin Jabesi Gílíádì. Ṣùgbọ́n wọn kò kárí gbogbo wọn.

15. Àwọn ènìyàn náà sì káàánú nítorí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, nítorí Olúwa fi àlàfo kan sílẹ̀ nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

16. Àwọn olórí ìjọ àwọn ènìyàn náà wí pé, “Kí ni àwa yóò ṣe láti rí aya fún àwọn ọkùnrin tí ó kù nígbà tí a ti pa gbogbo àwọn obìnrin Bẹ́ńjámínì run?”

17. Wọ́n sì wí pé, “Àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n là nínú àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ní láti ní ogún àti àrólé, kí ẹ̀yà kan nínú Ísírẹ́lì má ṣe di píparun kúrò ní orí ilẹ̀.

18. Àwa kò le fi àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ní aya, nítorí tí àwa ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣe ìbúra yìí pé: ‘Ègún ni fún ẹnikẹ́ni tí ó fi aya fún ẹnikẹ́ni nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.’ ”

Onídájọ́ 21