Onídájọ́ 20:40-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

40. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìkúukùú ẹ̀ẹ́fín bẹ̀rẹ̀ sí ní rú sókè láti inú ìlú náà wá, àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì yípadà wọ́n sì rí ẹ̀ẹ́fín gbogbo ìlú náà ń gòkè sí ojú ọ̀run.

41. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì yípadà sí wọn, ẹ̀rù gidigidi sì ba àwọn ará Bẹ́ńjámínì nítorí pé wọ́n mọ̀ pé àwọn wà nínú ewu.

42. Wọ́n sì sá níwáju àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí apá àṣálẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò le sálà kúrò lọ́wọ́ ogun náà. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí ó jáde láti inú àwọn ìlú wọn wá pa wọ́n run níbẹ̀.

Onídájọ́ 20