Nọ́ḿbà 9:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè nínú ihà Ṣínáì ní oṣù kìn-ín-ní ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì wí pé;

2. “Mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní àsìkò rẹ̀.

3. Ẹ ṣe é ní àsìkò rẹ̀ gan-an ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀.”

4. Mósè sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa pa àjọ ìrékọjá mọ́.

Nọ́ḿbà 9