Nọ́ḿbà 7:70-85 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

70. Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

71. Màlúù méjì, àgbò márùn-ùn, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fí rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ ọmọ Dánì.

72. Págíélì ọmọ Ókíránì, olórí àwọn ọmọ Áṣérì ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kọkànlá.

73. Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

74. Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

75. Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun.;

76. Akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

77. Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, tí wọn ó fí rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Págíélì ọmọ Ókíránì.

78. Áhírà ọmọ Énánì, olórí àwọn Náfítanì ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kejìlá.

79. Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì, àti àwokótó tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

80. Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì méwàá tí ó kún fún tùràrí;

81. Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

82. Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

83. Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Áhírà ọmọ Énánì.

84. Wọ̀nyí ni ọrẹ tí àwọn olórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ nígbà tí wọ́n ta òróró sí i lórí: àwo fàdákà méjìlá, àwokòtò méjìlá, àwo wúrà méjìlá.

85. Àwo fàdákà kọ̀ọ̀kan wọn àádóje (130) ṣékélì, àwokòtò kọ̀ọ̀kan sì wọn àádọ́rin (70). Àpapọ̀ gbogbo àwo fàdákà jẹ́ egbèjìlá ṣékélì (2,400) gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́.

Nọ́ḿbà 7