Nọ́ḿbà 6:22-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Olúwa sọ fún Mósè pé,

23. “Sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Báyìí ni kí ẹ ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹ sọ fún wọn pé:

24. “ ‘ “Kí Olúwa bùkún un yínKí ó sì pa yín mọ́.

25. Kí Olúwa kí o mú ojú rẹ̀ kí ó mọ́lẹ̀ sí i yín lára.Kí ó sì ṣàánú fún un yín.

26. Kí Olúwa bojú wò yín;Kí ó sì fún un yín ní àlàáfíà.” ’

27. “Báyìí ni wọn ó ṣe fi orúkọ mi sára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Èmi ó sì bùkún wọn.”

Nọ́ḿbà 6