27. Tí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ sì ri ní ìta ìlú náà, olùgbẹ̀san lè pa ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn láì jẹ́bi ẹ̀sùn ìpànìyàn.
28. Ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn gbọdọ̀ dúró nínú ìlú ìsásí títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú; lẹ́yìn ikú olórí àlùfáà, ni ó tó lè padà sí ibi tí dúkìá rẹ̀ wà.
29. “ ‘Wọ̀nyí ni ó jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún yín ní ìran yín tó ń bọ̀, ní ibikíbi tí ẹ bá ń gbé.
30. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn gbọdọ̀ kú gẹ́gẹ́ bí apànìyàn lórí ìjẹ́rìí àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí kanṣoṣo. Kì yóò jẹ́ri sí ẹnìkan láti pa.