Nọ́ḿbà 31:47-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

47. Lára ààbọ̀ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Mósè yan ọ̀kan lára àádọ́ta (50) ènìyàn àti ẹranko gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un. Ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì, tí ń ṣe olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.

48. Pẹ̀lú àwọn olórí tí ó wà lórí ẹgbẹẹgbẹ̀rin ogun náà, àti àwọn balógun ọrọọrún wá sọ́dọ̀ Mósè.

49. Wọ́n sì sọ fún un pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ti ka àwọn ọmọ ogun náà tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú wa, kò sì sí ìkọkan tó dín.

50. Nítorí náà làwa ṣe mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa, gbogbo ọrẹ wíwà tí a ní, wúrà, ẹ̀wọ̀n, àti júfù, àti òrùka: àmi, àti òrùka etí, àti ìlẹ̀kẹ̀ láti fi ṣe ètùtù fún ọkàn an wa níwájú Olúwa.”

51. Mósè àti Élíásárì àlùfáà, gba wúrà náà lọ́wọ́ ọ wọn pẹ̀lú gbogbo ohun iṣẹ́ ọ̀ṣọ́.

Nọ́ḿbà 31