1. Nígbà tí àwọn Ísírẹ́lì dúró ní Ṣítímù, àwọn ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Móábù,
2. tí ó pè wọ́n sí bi ẹbọ òrìṣà wọn. Àwọn ènìyàn náà jẹun wọ́n sì foríbalẹ̀ níwájú òrìṣà wọn.
3. Báyìí ni Ísírẹ́lì ṣe darapọ̀ mọ́ wọn tí wọ́n sì jọ ń sin Báálì ti Péórì. Ìbínú Olúwa sì ru sí wọn.
4. Olúwa sọ fún Mósè pé; “Mú gbogbo àwọn olórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, pa wọ́n kí o sì fi wọ́n kọ́ sórí igi ní gbangba nínú oòrùn níwájú Olúwa, kí ìbínú Olúwa lè kúrò ní ọ̀dọ̀ Ísírẹ́lì.”
5. Mósè sọ fún àwọn onídàájọ́ Ísírẹ́lì, “Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ pa arákùnrin rẹ̀ èyí tí ó darapọ̀ ní fífi orí balẹ̀ fún Báálì ti Peori.”