Nọ́ḿbà 23:20-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Èmi gba àṣẹ láti bùkún;Ó sì ti bùkún, èmi kò sì lè yípadà.

21. “Kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan nínú Jákọ́bù,kò sì rí búburú kankan nínú Ísírẹ́lì. Olúwa Ọlọ́run wọn sì wà pẹ̀lú wọn.Ìhó ọba sì wà pẹ̀lú wọn.

22. Ọlọ́run mú wọn jáde láti Éjíbítì wá,wọ́n ní agbára màlúù ẹhànnà.

23. Kò ní àfọ̀ṣẹ sí Jákọ́bù,tàbí àfọ̀ṣẹ sí àwọn Ísírẹ́lì.Nísinsìnyìí a ó sọ nípa ti Jákọ́bùàti Ísírẹ́lì, ‘Wo ohun tí Olúwa ti ṣe!’

24. Àwọn ènìyàn dìde bí abo kìnnìún;wọ́n dìde bí i kìnnìúntí kì í sinmi títí yóò fi pa ìkógún jẹtàbí mu ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó fi ara pa.”

25. Nígbà náà ni Bálákì sọ fún Bálámù pé, “O ko fi wọ́n bú tàbí bùkún wọn rárá!”

26. Bálámù dáhùn pé, “Ǹjẹ́ mi ò sọ fún ọ pé mo gbọdọ̀ Ṣe ohun tí Olúwa bá sọ?”

27. Nígbà náà Bálákì sọ fún Bálámù pé, “Wá jẹ́ kí èmi kí ó mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá yóò tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn kí ó fi wọ́n bú láti ibẹ̀ lọ.”

28. Bálákì gbé Bálámù wá sí orí òkè Péórì, tí ó kọjú sí ihà.

Nọ́ḿbà 23