4. Móábù sọ fún àwọn àgbààgbà Mídíánì pé, “Nísinsìnyìí ni àwọn wọ̀nyí yóò lá gbogbo ohun tí ó yí wa ká, bí màlúù ṣe ń jẹ koríko tí ó wà nínú oko.” Bẹ́ẹ̀ ni Bálákì ọmọ Ṣípórì, tí ó jẹ́ ọba Móábù nígbà náà,
5. rán oníṣẹ́ pé Bálámù ọmọ Béórì, tí ó wà ní Pétórì, ní ẹ̀bá odò ti ilẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ. Bálákì sọ pé:“Àwọn ènìyàn kan jáde wá láti Éjíbítì; wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ ayé wọ́n sì pa ibùdó súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi.
6. Nísinsìnyìí wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú, nítorí wọ́n ní agbára jù fún mi. Nípa ṣíṣe èyí èmi ó ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ yìí. Nítorí tí mo mọ̀ pé ìbùkún ni fún àwọn tí ìwọ bá bùkún, ìfibú sì ni ẹni tí ìwọ bá fi bú.”