24. Nígbà náà ángẹ́lì Olúwa dúró ní ojú ọ̀nà tóóró láàrin ọgbà àjàrà, pẹ̀lú ògiri ní ọ̀nà méjèèjì.
25. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí ángẹ́lì Olúwa, ó lẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ ògiri, ó sì rún ẹsẹ̀ Bálámù mọ́ ògiri. Nígbà náà, ó tún nàá, lẹ́ẹ̀kan sí i.
26. Nígbà náà ángẹ́lì Olúwa súnmọ́ wájú ó sì dúró níbi ọ̀nà tóóró níbi tí kò ti sí ọ̀nà láti yípadà, bóyá ní ọ̀tún tàbí òsì.
27. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí ángẹ́lì Olúwa, ó sì jókó ní abẹ́ Bálámù, inú sì bí i tó sì ná-àn pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀.
28. Nígbà náà Olúwa sí ẹnu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì sọ fún Bálámù pé, “Kí ni mo ṣe fún ọ tí o fi nà mí lẹ́ẹ̀mẹ́ta?”
29. Bálámù sọ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pé, “Nítorí ìwọ fi mí ṣẹ̀sín! Bí mo bá ní idà ní ọwọ́ ni èmi ì bá pa ọ́ nísinsin yìí.”
30. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sọ fún Bálámù pé, “Ṣé mi kì í ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ni, tí o máa ń gùn ní gbogbo ìgbà, láti ìgbà pípẹ́ wá? Ǹjẹ́ mo hu irú ìwà báyìí sí ọ rí?”“Rárá,” Ó dáhùn.