19. Nísinsìnyìí ẹ dúró níbí di ọjọ́ kejì gẹ́gẹ́ bí àwọn tókù ti ṣe nígbà náà èmi yóò mọ ohun tí Olúwa yóò tún sọ fún mi.”
20. Ní alẹ́ ọjọ́ náà Ọlọ́run sì tọ Bálámù wá ó sì sọ wí pé, “Nígbà tí ọkùnrin yìí ti wá pè ọ́, lọ pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ẹnu nǹkan tí mo sọ fún ọ ni kí o ṣe.”
21. Bálámù dìde ní òwúrọ̀, ó sì di ẹrù lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ òun pẹ̀lú àwọn ìjòyè Móábù.
22. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run bínú gidigidi, áńgẹ́lì Olúwa sì dúró lójú ọ̀nà láti dojú ìjà kọ ọ́. Bálámù ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ lọ, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì sì wà pẹ̀lú rẹ̀.
23. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì rí áńgẹ́lì Olúwa tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà tí a fà yọ ní ọwọ́ rẹ̀, ó kọjú kúrò ní ọ̀nà lọ sínú oko. Bálámù sì lù ú pé kí ó gbé òhun padà lọ sí ojú ọ̀nà.
24. Nígbà náà ángẹ́lì Olúwa dúró ní ojú ọ̀nà tóóró láàrin ọgbà àjàrà, pẹ̀lú ògiri ní ọ̀nà méjèèjì.
25. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí ángẹ́lì Olúwa, ó lẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ ògiri, ó sì rún ẹsẹ̀ Bálámù mọ́ ògiri. Nígbà náà, ó tún nàá, lẹ́ẹ̀kan sí i.
26. Nígbà náà ángẹ́lì Olúwa súnmọ́ wájú ó sì dúró níbi ọ̀nà tóóró níbi tí kò ti sí ọ̀nà láti yípadà, bóyá ní ọ̀tún tàbí òsì.
27. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí ángẹ́lì Olúwa, ó sì jókó ní abẹ́ Bálámù, inú sì bí i tó sì ná-àn pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀.
28. Nígbà náà Olúwa sí ẹnu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì sọ fún Bálámù pé, “Kí ni mo ṣe fún ọ tí o fi nà mí lẹ́ẹ̀mẹ́ta?”