Nọ́ḿbà 22:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rin ìrìnàjò lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù wọ́n sì pa ibùdó lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì tí ó kọjá lọ sí Jẹ́ríkò.

2. Nísinsìnyìí Bálákì ọmọ Sípórì rí gbogbo ohun tí àwọn Ísírẹ́lì ti ṣe sí àwọn ará Ámórì,

3. ẹ̀rù sì ba Móábù nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn wà níbẹ̀ nítòótọ́, Móábù kún fún ẹ̀rù nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

4. Móábù sọ fún àwọn àgbààgbà Mídíánì pé, “Nísinsìnyìí ni àwọn wọ̀nyí yóò lá gbogbo ohun tí ó yí wa ká, bí màlúù ṣe ń jẹ koríko tí ó wà nínú oko.” Bẹ́ẹ̀ ni Bálákì ọmọ Ṣípórì, tí ó jẹ́ ọba Móábù nígbà náà,

5. rán oníṣẹ́ pé Bálámù ọmọ Béórì, tí ó wà ní Pétórì, ní ẹ̀bá odò ti ilẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ. Bálákì sọ pé:“Àwọn ènìyàn kan jáde wá láti Éjíbítì; wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ ayé wọ́n sì pa ibùdó súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi.

Nọ́ḿbà 22