9. “Ẹni tó wà ní mímọ́ ni yóò kó eérù ọ̀dọ́ màlúù náà lọ sí ibi tí a yà sí mímọ́ lẹ́yìn ibùdó. Kí gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì kó o pamọ́ fún lílò fún omi ìwẹ̀nùmọ́. Ó jẹ́ ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
10. Ọkùnrin tí ó kó eérú ọ̀dọ́ abo màlúù náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti fún àwọn àlejò tí ó ń gbé láàrin wọn.
11. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́kan òkú ẹnikẹ́ni, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje.
12. Ó gbọ̀dọ̀ wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi ní ọjọ́ kẹ́ta àti ní ọjọ́ kéje; nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ pé kò wẹ ara rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kẹ́ta àti ní ọjọ́ kéje yóò jẹ́ aláìmọ́.
13. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnìkan tí kò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́, ó ba àgọ́ Olúwa jẹ́. A ó ké irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nítorí pé a kò tí ì wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ lé e lórí, ó jẹ́ aláìmọ́, àìmọ́ rẹ̀ sì wà lára rẹ̀.
14. “Èyí ni òfin tí ó jẹ mọ́ bí ènìyàn bá kú nínú àgọ́: Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ inú àgọ́ àti ẹni tí ó wà nínú àgọ́ yóò di aláìmọ́ fún ọjọ́ méje,
15. Gbogbo ohun èlò tí a kò bá fi ómẹ́rì dé ni yóò jẹ́ aláìmọ́.
16. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní ìta tí ó sì fi ọwọ́ kan ẹni tí a fi idà pa tàbí ẹni tí ó kú ikú àtọ̀runwá, tàbí bí ẹ̀nìkan bá fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí iṣà òkú, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje.
17. “Fún aláìmọ́ ènìyàn, mú eérú díẹ̀ lára eérú ọrẹ ìwẹ̀nùmọ́ sínú ìgò, kí o sì da omi tó ń sàn lée lórí.