Nọ́ḿbà 16:32-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. ilẹ̀ sì lanu ó sì gbé wọn mì pẹ̀lú gbogbo ará ilé wọn àti àwọn ènìyàn Kórà àti gbogbo ohun tí wọ́n ní.

33. Gbogbo wọn sì sọ̀kalẹ̀ sínú ibojì wọn láàyè pẹ̀lú ohun gbogbo tí wọ́n ní, ilẹ̀ sì padé mọ́ wọn, wọ́n sì ṣègbé kúrò láàrin ìjọ ènìyàn.

34. Nígbà tí àwọn yóòkù gbọ́ igbe wọn, wọ́n sálọ, wọ́n wí pé, “Ilẹ̀ yóò gbé àwa náà mì pẹ̀lú.”

35. Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa ó sì run àádọ́tàlénígba ọkùnrin (250) tí wọ́n mú tùràrí wá.

36. Olúwa sọ fún Mósè pé,

Nọ́ḿbà 16