Nọ́ḿbà 16:20-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Olúwa sì sọ fún Mósè àti Árónì pé,

21. “Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn wọ̀nyí, kí ń ba à le pa wọ́n run lẹ́ẹ̀kan náà.”

22. Ṣùgbọ́n Mósè àti Árónì dojúbolẹ̀ wọ́n sì kígbe sókè pé, “Ọlọ́run, Ọlọ́run ẹ̀mi gbogbo ènìyàn, Ìwọ ó wa bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn nígbà tó jẹ́ pé ẹnì kan ló ṣẹ̀?”

23. Olúwa tún sọ fún Mósè pé,

24. “Sọ fún ìjọ ènìyàn pé, ‘Kí wọ́n jìnnà sí àgọ́ Kórà, Dátanì àti Ábírámù.’ ”

Nọ́ḿbà 16