8. “ ‘Nígbà tí ẹ bá sì pèsè ọ̀dọ́ akọ màlúù fún ọrẹ tàbí ẹbọ sísun, láti fi san ẹ̀jẹ́ tàbí fún ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa,
9. Ẹni náà yóò mú ọ̀dọ́ akọ màlúù náà wá pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ, ìdá sí mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúná tí a fi ìdajì òṣùwọ̀n òróro pò.
10. Kí ó tún mú ìdajì òsùwọ̀n wáìnì wá fún ọrẹ ohun mímu. Yóò jẹ́ ọrẹ àfinásun, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
11. Báyìí ni kí ẹ se pèṣè ọ̀dọ́ akọ màlúù tàbí àgbò, ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí ọmọ ewúrẹ́.
12. Ẹ se bẹ́ẹ̀ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, iyekíye tí ẹ̀yin ì bá à pèsè.