Nọ́ḿbà 15:39-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Wajawaja yìí ni ẹ sì máa wò láti lè mú yín rántí gbogbo òfin Olúwa, kí ẹ bá à lè ṣe wọ́n, kí ẹ sì má bá à ṣe àgbérè nípa títẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn àti ojú yín.

40. Nígbà náà ni ẹ ó gbọ́ran láti pa gbogbo òfin mi mọ́, ẹ ó sì jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run yín.

41. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti Éjíbítì láti jẹ́ Ọlọ́run yín. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”

Nọ́ḿbà 15