16. Òfin kan àti ìlànà kan ni yóò wà fún yín àti fún àwọn àlejò tí ń gbé láàrin yín.’ ”
17. Olúwa sọ fún Mósè pé,
18. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísirẹ́lì pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí mo ń mú yín lọ.
19. Tí ẹ sì jẹ oúnjẹ ilẹ̀ náà, ẹ mú nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ìgbésókè wá fún Olúwa.
20. Ẹ mú àkàrà wá nínú àkọ́so oúnjẹ yín wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ìgbésókè sí Olúwa, ọrẹ láti inú ilẹ̀ ìpakà yín.
21. Nínú àkọ́so oúnjẹ yín ni kí ẹ ti máa mú ọrẹ ìgbésókè yìí fún Olúwa.
22. “ ‘Bí ẹ bá kùnà láìròtẹ́lẹ̀ láti pa àwọn òfin tí Olúwa fún Mósè mọ́:
23. Èyí ni gbogbo òfin tí Olúwa fún yín láti ẹnu Mósè láti ọjọ́ tí Olúwa ti fún yín àti títí dé ìran tó ń bọ̀.