Nọ́ḿbà 12:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Olúwa sì dá Mósè lóhùn, “Bí bàbá rẹ̀ bá tutọ́ sí i lójú, ojú kò wa ní í tì í fún ọjọ́ méje? Dá a dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, lẹ́yìn èyí ki a tó ó le mú wọlé.”

15. Míríámù sì dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, àwọn ènìyàn kò sì tẹ̀ ṣíwájú nínú ìrìnàjò wọn títí tí Míríámù fi wọ inú ibùdó padà.

16. Lẹ́yìn èyí, àwọn ènìyàn kúrò ní Hásérótì, wọ́n sì pa ibùdó sí Aginjù Páránì.

Nọ́ḿbà 12