Nọ́ḿbà 12:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Míríámù àti Árónì sọ̀rọ̀ òdì sí Mósè nítorí pé ó fẹ́ obìnrin ará Etiópíà.

2. Wọ́n sì wí pé, “Nípa Mósè nìkan ni Olúwa ti sọ̀rọ̀ bí, kò ha ti ipa wa sọ̀rọ̀ bí?” Olúwa sì gbọ́ èyí.

3. (Mósè sì jẹ́ ọlọ́kàn tútù ènìyàn ju gbogbo ènìyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé lọ).

Nọ́ḿbà 12