Nọ́ḿbà 10:29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
Mósè sì sọ fún Hóbábì ọmọ Réúélì ará Mídíánì tí í se àna Mósè pé, “A ń gbéra láti lọ sí ibi tí Olúwa sọ pé, ‘Èmi ó fi fún un yín.’ Bá wa lọ àwa ó se ọ́ dáradára nítorí pé Olúwa ti ṣèlérí ohun rere fún Ísírẹ́lì.”