Nọ́ḿbà 1:52-54 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

52. kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa àgọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn olúkúlùkù ní ibùdó tirẹ̀ lábẹ́ ọ̀págun tirẹ̀.

53. Àwọn ọmọ Léfì yóò jẹ́ alábojútó àti olùtọ́jú Àgọ́ Ẹ̀rí náà, kí ìbínú má ba à sí lára ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; kí àwọn ọmọ Léfì sì máa ṣe ìtọ́jú Àgọ́ Ẹ̀rí náà.”

54. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

Nọ́ḿbà 1