4. Nígbà náà ni Jéṣúà, àti Bánì, Kádímíélì, Ṣebaníà, Bunnì, Ṣeribíà, Bánì àti Kénánì gòkè dúró lórí àwọn àtẹ̀gùn àwọn ọmọ Léfì, wọ́n si fi ohùn rara kígbe sí Olúwa Ọlọ́run wọn
5. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Léfì: Jéṣúà, Bánì, Háṣábínéáyà, Ṣérébáyà, Hódáyà, Ṣébánáyà àti Pétaíáyà—wí pé: “Ẹ dìde ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó wà láé àti láéláé.”“Ìbùkún ni fún orúkọ ọ̀ rẹ tí ó ní ògo, kí ó sì di gbígbéga ju gbogbo ìbùkún àti ìyìn lọ.
6. Ìwọ nìkan ni Olúwa. Ìwọ ni ó dá àwọn ọ̀run, àní àwọn ọ̀run tí ó ga jù àti àìlónkà ogun ọ̀run wọn, ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú un rẹ̀, àwọn òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú un wọn. Ìwọ fún gbogbo wọn ní ìyè àìlónkà àwọn ogun ọ̀run sì ń sìn ọ́.
7. “Ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run, tí ó yan Ábúrámù tí ó sì mú u jáde láti Úrì ti Kálídéà, tí ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ábúráhámù.
8. Ìwọ sì rí í pé ọkàn rẹ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí ọ, ìwọ sì dá májẹ̀mú pẹ̀lú u rẹ̀ láti fi ilẹ̀ àwọn aráa Kénánì, Hítì, Ámórì, Pérísì, Jébúsì àti Gírígásì fún irú àwọn ọmọ rẹ̀. Ìwọ ti pa ìpinnu rẹ̀ mọ́ nítorí tí ìwọ jẹ́ olódodo.
9. “Ìwọ rí ìpọ́njú àwọn baba ńlá wa ní Éjíbítì; ìwọ gbọ́ igbe ẹkún un wọn ní òkun pupa.