17. Wọ́n kọ̀ láti fetí sílẹ̀, wọ́n sì kùnà láti rántí iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ṣe ní àárin wọn. Wọ́n ṣe agídí, nínú ìṣọ̀tẹ̀ẹ wọn, wọ́n yan olórí láti padà sí oko ẹrúu wọn. Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì, olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́. Nítorí náà ìwọ kò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀,
18. Kódà nígbà tí wọ́n yá ère dídá (ère ọmọ màlúù) fún ara wọn, tí wọ́n sì wí pé, Èyí ni Ọlọ́run rẹ tí ó mú ọ gòkè láti Éjíbítì wá; tàbí nígbà tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì.
19. “Nítorí àánú ńláà rẹ, ìwọ kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ní ihà. Ní ọ̀sán ọ̀pọ̀ ìkùùkuu kò kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn láti ṣe amọ̀nà an wọn, tàbí ọ̀pọ̀ iná láti tàn sí wọn ní òru ní ọ̀nà tí wọn yóò rìn.
20. Ìwọ fi ẹ̀mí rere rẹ fún wọn láti kọ́ wọn. Ìwọ kò dá mánà rẹ dúró ní ẹnu wọn, ó sì fún wọn ní omi fún òrùngbẹ.
21. Fún ogójì ọdún ni ìwọ fi bọ́ wọn ní ihà; wọn kò ṣe aláìní ohunkóhun, aṣọ wọn kò gbó bẹ́ẹ̀ ni ẹṣẹ̀ wọn kò wú.
22. “Ìwọ fi àwọn ìjọba àti àwọn orílẹ̀ èdè fún wọn, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ náà fún wọ́n. Wọ́n sì gba ilẹ̀ ọba Ṣíhónì aráa Hésíbónì àti ilẹ̀ ógù ọba Báṣánì.