15. Ìwọ fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá nígbà tí ebi ń pa wọ́n àti nígbà òrùngbẹ o fún wọn ní omi láti inú àpáta; ó sì sọ fún wọn pé, kí wọ́n lọ láti lọ gba ilẹ̀ náà tí ìwọ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fi fún wọn.
16. “Ṣùgbọ́n àwọn, baba ńláa wa, wọ́n ṣe ìgbéraga, wọ́n sì ṣe agídí, wọn kò sì tẹríba fún àwọn ìlànà rẹ.
17. Wọ́n kọ̀ láti fetí sílẹ̀, wọ́n sì kùnà láti rántí iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ṣe ní àárin wọn. Wọ́n ṣe agídí, nínú ìṣọ̀tẹ̀ẹ wọn, wọ́n yan olórí láti padà sí oko ẹrúu wọn. Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì, olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́. Nítorí náà ìwọ kò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀,
18. Kódà nígbà tí wọ́n yá ère dídá (ère ọmọ màlúù) fún ara wọn, tí wọ́n sì wí pé, Èyí ni Ọlọ́run rẹ tí ó mú ọ gòkè láti Éjíbítì wá; tàbí nígbà tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì.
19. “Nítorí àánú ńláà rẹ, ìwọ kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ní ihà. Ní ọ̀sán ọ̀pọ̀ ìkùùkuu kò kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn láti ṣe amọ̀nà an wọn, tàbí ọ̀pọ̀ iná láti tàn sí wọn ní òru ní ọ̀nà tí wọn yóò rìn.