4. Akọ̀wé Ẹ́sírà dìde dúró lórí i pẹpẹ ìdúrólé tí a fi igi kàn fún ètò yìí. Ní ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀ ọ̀tún ni Mátítayà, Ṣémà, Ánáyà, Úráyà, Hílíkáyà àti Máṣéíyà gbé dúró sí, ní ẹ̀gbẹ́ òsìi rẹ̀ ní Pédáíyà, Míṣíhẹ́lì, Málíkíjà, Hásúmù, Háṣábádánà, Ṣekaráyà àti Mésúlámù dúró sí.
5. Ẹ́sírà sí ìwé náà, gbogbo ènìyàn sì le rí í nítorí ó dúró níbi tí ó ga ju gbogbo ènìyàn lọ; bí ó sì ti sí ìwé náà, gbogbo ènìyàn dìde dúró.
6. Ẹ́sírà yin Olúwa, Ọlọ́run alágbára; gbogbo ènìyàn gbé ọwọ́ọ wọn sókè, wọ́n sì wí pé “Àmín! Àmín!” Nígbà náà ni wọ́n wólẹ̀ wọ́n sì sin Olúwa ní ìdojúbolẹ̀.
7. Àwọn Léfì-Jéṣúà, Bánì, Ṣérébáyà, Jámínì, Ákúbù, Ṣábétaì, Hódáyà, Máséyà, Kélítà, Aṣaráyà, Jóṣábádì, Hánánì àti Pereláyà—kọ́ wọn ni òfin náà bí àwọn ènìyàn ṣe wà ní ìdúró síbẹ̀.