Ní ẹnu ibodè oríṣun wọ́n ti ń lọ tààrà sí ọ̀nà ní orí àtẹ̀gùn ìlú Dáfídì ní orí òkè tí ó kángun sí odi, wọ́n sì gba ẹ̀gbẹ́ ilée Dáfídì kọjá títí dé ẹnu ibodè omi ní ìhà ìlà oòrùn.