Nehemáyà 10:35-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. “Àwa tún gbà ojuṣe láti mú àkọ́so àwọn èso wa wá àti gbogbo èso igi wá ní ilé Olúwa.

36. “Gẹ́gẹ́ bí a sì ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin, àwa yóò mú àkọ́bí àwọn ọmọkùnrin wa, ti ohun ọ̀sìn wa, ti àwọn abo màlúù àti ti àwọn àgùntàn wa, wá sí ilé Ọlọ́run wa, fún àwọn àlùfáà tí ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀.

37. “Síwájú sí i, àwa yóò mú àkọ́so oúnjẹ ilẹ̀ wa ti ọrẹ oúnjẹ (ọkà), ti gbogbo èṣo àwọn igi àti ti wáìnì túntún wa àti ti òróró wá sí yàrá ìpamọ́ ilé Ọlọ́run wa àti fún àwọn àlùfáà. Àwa yóò sì mú ìdámẹ́wàá ohun ọ̀gbìn wá fún àwọn ọmọ Léfì, nítorí àwọn ọmọ Léfì ni ó ń gba ìdáwẹ́wàá ní gbogbo àwọn ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́.

38. Àlùfáà tí o ti ìdílé Árónì wá ni yóò wá pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì nígbà tí wọ́n bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Léfì yóò sì mú ìdámẹ́wàá ti ìdámẹ́wàá náà wá sí ilé Ọlọ́run, sí yàrá ìpamọ́ inú ilé ìṣúra.

39. Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, àti àwọn ọmọ Léfì gbọdọ̀ mú ọrẹ oúnjẹ (ọkà), wáìnì túntún àti òróró wá sí yàrá ìpamọ́ níbi tí a pa ohun èlò ibi mímọ́ mọ́ sí àti ibi tí àwọn àlùfáà-tí-ń ṣe-ìránṣẹ́-lọ́wọ́, àwọn aṣọ́nà àti àwọn akọrin máa rí dúró sí.“Àwa kì yóò gbàgbé tàbí ṣe àìbìkítà nípa ilé Ọlọ́run wa.”

Nehemáyà 10