Nehemáyà 10:33-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Nítorí oúnjẹ tí ó wà lóríi tábìlì; nítorí ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun ṣíṣun ìgbà gbogbo; nítorí ọrẹ ọjọ́ ìsimi, ti àyájọ́ oṣù tuntun àti àṣè tí a yàn; nítorí ọrẹ mímọ́; nítorí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì; àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa.

34. “Àwa, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti àwọn ènìyàn náà ti dìbò láti pinnu ìgbà tí olúkúlùkù àwọn ìdílé yóò mú ọrẹ igi wá láti ṣun lọ́ríi pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa sí ilé Ọlọ́run wa, ní àkókò tí a yàn ní ọdọọdún. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin.

35. “Àwa tún gbà ojuṣe láti mú àkọ́so àwọn èso wa wá àti gbogbo èso igi wá ní ilé Olúwa.

36. “Gẹ́gẹ́ bí a sì ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin, àwa yóò mú àkọ́bí àwọn ọmọkùnrin wa, ti ohun ọ̀sìn wa, ti àwọn abo màlúù àti ti àwọn àgùntàn wa, wá sí ilé Ọlọ́run wa, fún àwọn àlùfáà tí ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀.

Nehemáyà 10