Náhúmù 3:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ègbé ni fún ìlú ẹ̀jẹ̀ nì,gbogbo rẹ̀ kún fún èké,àti olè,ìja kò kúrò!

2. Ariwo pàṣán àti ariwokíkùn kẹ̀kẹ́ ogunàti jíjó ẹṣin àti gbígbọ̀nkẹ̀kẹ́ ogun jìgìjìgì!

3. Ológun orí ẹṣin ń fi ìgbónáraju ìdà wọn mọ̀nàmọ̀nàọ̀kọ̀ rẹ̀ ti ń dán yanran sí òkè!Ọ̀pọ̀lọpọ̀ si ní àwọn ẹni tí a pa,àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkú;òkú kò si ni òpin;àwọn ènìyàn sì ń kọsẹ̀ lára àwọn òkú.

4. Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn panṣágààgbèrè tí ó rójú rere gbà,Iyá àjẹ́ tí ó sọ́ àwọn orilẹ̀-èdè di ẹrúnipa àgbèrè rẹ̀àti àwọn ìdílé nipa ìṣe àjẹ́ rẹ̀.

Náhúmù 3