6. A ó sí ìlẹ̀kùn àwọn odò wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀,a ó sì mú ààfin náà di yíyọ́.
7. A pa á láṣẹ pé ìlú náà Èyí tí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ni kí a kó ní ìgbèkùn lọ.A ó sì mú un gòkè wáàti awọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ yóò ti ohùn bí ti oriri, ṣe amọ̀nà rẹ̀,wọn a sì máa lu àyà wọn.
8. Nínéfè dàbí adágún omi,tí omi wọn sì ń gbẹ́ ẹ lọ.“Dúró! Dúró!” ni wọ́n ó máa kígbe,ṣùgbọ́n ẹnikankan kì yóò wo ẹ̀yìn.
9. “Ẹ kó ìkógun fàdákà!Ẹ kó ìkógun wúrà!Ìṣúra wọn ti kò lópin náà,àti ọrọ̀ kúrò nínú gbogbo ohun èlò ti a fẹ́!”