Náhúmù 1:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Láti ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ Nínéfè, ni ẹnìkan ti jáde wátí ó ń gbérò ibi sí Olúwati ó sì ń gbìmọ̀ búburú.

12. Báyìí ni Olúwa wí:“Bí wọ́n tilẹ̀ pé, tí wọ́n sì pọ̀ níye,Ṣùgbọ́n, báyìí ní a ó ké wọn lulẹ̀,nígbà tí òun ó bá kọ́já.Bí mo tilẹ̀ ti pọ́n ọ lójú ìwọ Júdà, èmi kì yóò pọ́n ọ lójú mọ́.

13. Nísinsin yìí ni èmi yóò já àjàgà wọn kúrò ní ọrùn rẹèmi yóò já sẹkẹ́sẹkẹ̀ rẹ dànù.”

14. Olúwa ti fi àṣẹ kan lélẹ̀ nítorí tìrẹ Nínéfè:“Ìwọ kì yóò ni irú ọmọ láti máa jẹ́ orúkọ rẹ mọ́,Èmi yóò pa ère fínfín àti ère dídà runtí ó wà nínú tẹ́ḿpílì àwọn ọlọ́run rẹ.Èmi yóò wa ibojì rẹ,nítorí ẹ̀gbin ni ìwọ.”

15. Wò ó, lórí àwọn okè,awọn ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìròyin ayọ wá,ẹni tí ó ń kéde àlàáfíà,Ìwọ Júdà, pa àṣẹ rẹ tí ó ní ìrònú mọ́,kí ó sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ.Àwọn ènìyàn búburú kì yóò sì gbógun tì ọ́ mọ́;Wọn yóò sì parun pátapáta.

Náhúmù 1