29. Wọ́n kígbe lóhùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tàwa tìrẹ, Ìwọ Ọmọ Ọlọ́run? Ìwọ ha wá láti dá wa lóró ṣáájú ọjọ́ tí a yàn náà?”
30. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá tí ń jẹ̀ ń bẹ ní ọ̀nà jíjìn díẹ̀ sí wọn
31. Àwọn ẹ̀mí-èsú náà bẹ̀ Jésù wí pé, “Bí ìwọ bá lé wa jáde, jẹ́ kí àwa kí ó lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ yìí.”