Mátíù 8:26-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. È é se ti ẹ̀yin fi ń bẹ̀rù?” Nígbà náà ní ó dìde dúró, ó sì bá ìjì àti rírú òkun náà wí. gbogbo rẹ̀ sì pa rọ́rọ́.

27. Ṣùgbọ́n ẹnu yà àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì béèrè pé, “Irú ènìyàn wo ni èyí? kódà ìji-líle àti rírú omi òkun gbọ́ tirẹ̀?”

28. Nígbà ti ó sì dé àpa kejì ní ilẹ̀ àwọn ara Gádárénésì, àwọn ọkùnrin méjì ẹlẹ́mìí-èṣù ti inú ibojì wá pàdé rẹ̀. Wọn rorò gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò le kọjá ní ọ̀nà ibẹ̀.

Mátíù 8