6. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, wọ inú iyàrá rẹ lọ, sé ilẹ̀kùn mọ́ ara rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ ẹni tí ìwọ kò rí. Nígbà náà ni Baba rẹ tí ó mọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ rẹ, yóò san án fún ọ.
7. Ṣùgbọ́n nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe àtúnwí asán bí àwọn aláìkọlà, nítorí wọn rò pé a ó titorí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ gbọ́ tiwọn.
8. Ẹ má ṣe dà bí i wọn, nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ ohun tí ẹ ṣe aláìní, kí ẹ tilẹ̀ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
9. “Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ ṣe máa gbàdúrà:“ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run,ọ̀wọ̀ fún orukọ yín,