Mátíù 26:3-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ní àsìkò tí Jésù ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn olórí àlùfàá àti àwọn àgbààgbà kó ara wọn jọ ní ààfin olórí àlùfàá náà tí à ń pè ní Káíáfà.

4. Láti gbèrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n yóò fi mú Jésù pẹ̀lú ẹ̀tàn, kí wọn sì pa á.

5. Ṣùgbọ́n wọ́n fohùn ṣọ̀kan pé, “Kì í ṣe lásìkò àsè àjọ ìrékọjá, nítorí rògbòdìyàn yóò ṣẹlẹ̀.”

6. Nígbà tí Jésù wà ní Bẹ́tánì ní ilé ọkùnrin tí à ń pè ní Símónì adẹ́tẹ̀;

7. Bí ó ti ń jẹun, obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìgò òróró ìkunra iyebíye, ó sì dà á sí i lórí.

8. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yin rí i, inú bí wọn. Wọ́n wí pé, “Irú ìfowóṣòfò wo ni èyí?

9. È é ha ti ṣe, obìnrin yìí ìbá tà á ní owó púpọ̀, kí a sì fi owó náà fún àwọn aláìní.”

Mátíù 26