Mátíù 25:4-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Àwọn ọlọ́gbọ́n mú epo sínú kólòbó dání pẹ̀lú àtùpà wọn.

5. Nígbà tí ọkọ ìyàwó pẹ́, gbogbo wọn tòògbé wọn sì sùn.

6. “Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, igbe ta sókè, ‘Wò ó, ọkọ ìyàwó ń bọ̀, ẹ jáde sóde láti pàdé rẹ̀.’

7. “Nígbà náà ni àwọn wúńdíá sì tají, wọ́n tún àtùpà wọn ṣe.

Mátíù 25