Mátíù 24:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Lóòótọ́, àfi bí a ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú, gbogbo ẹ̀dá alààyè yóò ṣègbé. Ṣùgbọ́n nítorí ti àwọn àyànfẹ́ ni a ó fi ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú.

23. Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Wo Kírísítì náà,’ tàbí pé ó ti farahàn níhìn-ín tàbí lọ́hùn-ún, ẹ má ṣe gbà á gbọ́.

24. Nítorí àwọn èké Kírísítì àti àwọn èké wòlíì yóò dìde. Wọn yóò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àti ìyanu. Bí ó bá lè ṣe é ṣe wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run pàápàá jẹ.

25. Wò ó, mo ti kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀.

Mátíù 24