Mátíù 24:15-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. “Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìṣọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Dáníẹ́lì sọ, tí ó bá dúró ní ibi mímọ́, (ẹni tí ó bá kà á, kí òye kí ó yé e).

16. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn tí ó wà ní Jùdíà sá lọ sí àwọn orí òkè.

17. Kí ẹni tí ó wà lórí ilé rẹ̀ má ṣe sọ̀ kalẹ̀ wá mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀.

18. Kí àwọn tí ó sì wà lóko má ṣe darí wá sí ilé láti mú àwọn aṣọ wọn.

19. Ṣùgbọ́n àánú ṣe mí fún àwọn obìnrin ti ó lóyún, àti fún àwọn tí ó ń fún ọmọ lọ́mú ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì!

20. Ẹ sì máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣe jẹ́ ìgbà òtútù, tàbí ọjọ́ ìsinmi.

21. Nítorí ìpọ́njú ńlá yóò wà, irú èyí tí kò tí ì sẹlẹ̀ láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wá títí di ìsinsìn yìí irú rẹ̀ kì yóò sì sí.

22. Lóòótọ́, àfi bí a ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú, gbogbo ẹ̀dá alààyè yóò ṣègbé. Ṣùgbọ́n nítorí ti àwọn àyànfẹ́ ni a ó fi ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú.

23. Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Wo Kírísítì náà,’ tàbí pé ó ti farahàn níhìn-ín tàbí lọ́hùn-ún, ẹ má ṣe gbà á gbọ́.

Mátíù 24