Mátíù 23:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ẹ má ṣe pe ẹnikẹ́ni ní baba yín ni ayé yìí, nítorí baba kan náà ni ẹ ní tí ó ń bẹ ní ọ̀run.

10. Kí a má sì ṣe pè yín ní Olùkọ́ nítorí Olùkọ́ kan ṣoṣo ni ẹ̀yin ní, òun náà ni Kírísítì.

11. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá pọ̀ jù nínú yín, ni yóò jẹ́ ìránṣẹ́ yín.

Mátíù 23