30. Àwọn àpósítélì ko ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ Jésù, wọ́n sí ròyìn ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe àti ohun gbogbo tí wọ́n ti kọ́ni.
31. Nígbà tí Jésù rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ ti wọ́n sì ń bọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí ààyè fún wọn láti jẹun, ó si wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a kúrò láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí fún ìgbà díẹ̀, kí a sì sinmi.”
32. Nítorí náà, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibi tí ó parọ́rọ́.
33. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ènìyàn ni o rí wọn nígbà tí wọ́n ń lọ. Àwọn wọ̀nyí sì tí ó wá láti ìlú ńlá gbogbo sáré gba etí òkun, wọ́n sì ṣe déédé wọ́n bí wọ́n ti gúnlẹ̀ ní èbúté.
34. Bí Jésù ti ń sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ náà, ó bá ọ̀pọ̀ ènìyàn bí i tí àtẹ̀yìnwá, tí wọ́n ti ń dúró dè e. Ó káàánú fún wọn, nítorí wọ́n dàbí àgùntàn tí kò ní olùtọ́jú. Ó sì kọ́ wọn ni ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó yẹ kí wọ́n mọ̀.