Máàkù 4:30-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Jésù sì tún wí pé, “Kí ni kí èmi fi ìjọba Ọlọ́run wé? Òwe wo ni kí èmi fi ṣe àkàwé rẹ̀?

31. Ó dàbí èso hóró Músítádì kan, lóòótọ́, ó jọ ọ̀kan níńu àwọn èso tí ó kéré jùlọ ti a gbin sínú ilẹ̀.

32. Ṣíbẹ̀, nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbà sókè, ó gbilẹ̀, ó sì di títóbi ju gbogbo ewéko inú ọgba yókù lọ. Ó sì ya ẹ̀ka ńlá níbi tí àwọn ẹyẹ ọ̀run lè kọ́ ìtẹ́ wọn sí, kí wọn sì rí ìdáàbò-bò.”

33. Òun lo ọ̀pọ̀ irú òwe wọ̀nyí láti fi kọ́ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n bá ti ń fẹ́ láti ní òye tó.

34. Kìkì òwe ni Jésù fi ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́ ìta gbangba rẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, nígbà tí ó bá sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, òun a sì sọ ìtumọ̀ ohun gbogbo.

35. Nígbà tí alẹ́ lẹ́, Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá sí apákejì.”

36. Nígbà tí wọn ti tú ìjọ ká, wọ́n si gbà á sínú ọkọ̀ ojú omi gẹ́gẹ́ bí ó ti wà. Àwọn ọkọ̀ ojú-omi kékeré mìíràn sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀.

37. Ìji líle ńlá kan sì dìde, omi sì ń bù sínú ọkọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ fi bẹ̀rẹ̀ síi kún fún omi, ó sì fẹ́rẹ rì.

38. Jésù ti sùn lọ lẹ́yìn ọkọ̀, ó gbé orí lé ìrọ̀rí. Wọ́n sì jí i lóhùn rara wí pé, “Olùkọ́ni, tàbí ìwọ kò tilẹ̀ bìkítà pé gbogbo wa fẹ́ rì?”

39. Ó dìde, ó bá ìjì líle náà wí, ó sì wí fún òkun pé, “Dákẹ́ jẹ́ẹ́,” ìjì náà sì dá, ìparọ́rọ́ ńlá sì wà.

40. Lẹ́yìn náà, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Èése tí ẹ̀yin fi ń ṣojo bẹ́ẹ̀? Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ì ní ìgbàgbọ́ ṣíbẹ̀síbẹ̀?”

41. Ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni èyí, tí ìjì àti òkun ń gbọ́ tirẹ̀!”

Máàkù 4