3. wọn sì ń bi ara wọn léèrè pé, “Ta ni yóò yí òkúta náà kúrò lẹ́nu ibojì fún wa?”
4. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn sì wò ó, wọ́n rí i pé a ti yí òkúta tí ó tóbi gidigidi náà kúrò.
5. Nígbà tí wọ́n sì wọ inú ibojì náà, wọ́n rí ọ̀dọ́mọkùnrin kàn tí ó wọ aṣọ funfun, ó jókòó ní apá ọ̀tún, ẹnú sì yà wọn.
6. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù: Ẹ̀yin ń wá Jésì tí Násárẹ́tì, tí a kàn mọ́ àgbélébùú. Ó jíǹde! Kò sí níhìnín yìí mọ́, Ẹ wo ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.
7. Ṣùgbọ́n ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ títí kan Pétérù wí pé, ‘Òun ti ń lọ ṣíwájú yín sí Gálílì. Ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti rí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún yín.’ ”