Máàkù 15:32-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Jẹ́ kí Kírísítì, Ọba Ísírẹ̀lì, sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélèbùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́.” Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀.

33. Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsàn-án.

34. Ní wákàtí kẹsàn-án ni Jésù kígbe sókè ní ohùn rara, ó ní, “ÈLÓÍ, ÈLÓÍ, LÀMÁ SÀBÁKÍTANÍ?” ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”

35. Nígbà tí àwọn kan nínú àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Wò ó ó ń pe Èlíjà.”

36. Nígbà náà ni ẹnìkan wá sáré lọ ki kàn-ìn-kàn-ìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi lé orí ọ̀pá, ó sì nà án sí Jésù kí ó lè mu ún. Ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a máa wò ó, bóyá Èlíjà yóò wá sọ̀ ọ́ kalẹ̀.”

37. Jésù sì tún kígbe soke ni ohùn rara, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.

38. Aṣọ ìkélé tẹ́ḿpìlì sì fàya sí méjì láti òkè dé ìsàlẹ̀.

39. Nígbà tí balógun ọ̀rún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ ọ̀dọ̀ Jésù rí i tí kígbe sókè báyìí tí ó sì èémí ìgbẹ̀yìn, ó wí pé, “Dájúdájú Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí í se.”

40. Àwọn obìnrin kan wà níbẹ̀ pẹ̀lú, tí wọ́n ń najú wò ó láti òkèèrè. Màríà Magidalénì wà lára àwọn obìnrin náà, àti Màríà ìyá Jákọ́bù kékeré àti ti Jósè àti, Ṣálómè.

41. Àwọn wọ̀nyí, nígbà tí ó wà ní Gálílì máa ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n a sì máa ṣe ìranṣẹ́ fún un àti ọ̀pọ̀ obìnrin mìíràn tí wọ́n sì bá a gòkè wá sí Jerúsálémù.

Máàkù 15