Máàkù 11:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bí wọ́n ti súnmọ́ Bẹ́tífágè àti Bẹ́tanì ní ẹ̀yìn odi ìlú Jerúsálémù, wọ́n dé orí òkè ólífì. Jésù rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ṣíwájú.

2. Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tó wà lọ́hùn-ún nì. Nígbà tí ẹ bá sì wọlé, ẹ̀yin yóò rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a so mọ́lẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ì tí i gùn rí. Ẹ tú u, kí ẹ sì mú wá síhìn-ín.

3. Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń se èyí?’ Ẹ sọ fún un pé, ‘Olúwa ní í fi ṣe, yóò sì dá a padà síbí láìpẹ́.’ ”

Máàkù 11