Lúùkù 9:34-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Bí ó ti ń sọ báyìí, ìkùukù kan wá, ó ṣíji bò wọ́n: ẹ̀rù sì bà wọ́n nígbà tí wọ́n ń wọ inú ìkùukù lọ.

35. Ohùn kan sì ti inú ìkùukùu wá wí pé, “Èyí yìí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.”

36. Nígbà tí ohùn náà sì dákẹ́, Jésù nìkan ṣoṣo ni a rí. Wọ́n sì pa á mọ́, wọn kò sì sọ ohunkóhun tí wọ́n rí fún ẹnikẹ́ni ní ọjọ́ wọ̀nyí.

Lúùkù 9